‏ 1 Corinthians 10

Ìkìlọ̀ láti inú ìtàn àwọn ọmọ Israẹli

1 aNítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú aginjù. Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn nípa rírán ìkùùkuu síwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi Òkun pupa já. 2 bA lè pe eléyìí ní ìtẹ̀bọmi ti Mose nínú ìkùùkuu àti nínú omi Òkun. 3 cNípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. 4 dWọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára. 5 eṢùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.

6 fÀwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. 7 gKí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” 8 hBẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. 9 iBẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. 10 jBẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.

11Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú. 13 kKò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.

Oúnjẹ òrìṣà àti oúnjẹ alẹ́ Olúwa

14 lNítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà. 15Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnrarẹ̀ ohun tí mo sọ. 16 mǸjẹ́ ago ìdúpẹ́ nípasẹ̀ èyí tí a ń dúpẹ́ fún, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín nínú ara Kristi bi? 17Nítorí àkàrà kan ni ó ń bẹ, àwa tí a pọ̀ níye, tí a sì jẹ ara kan ń pín nínú àkàrà kan ṣoṣo.

18 nẸ wo Israẹli nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha ṣe alábápín pẹpẹ bí? 19Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí? Ṣé pé ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan? 20 oRárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rú ẹbọ wọn fi fun àwọn ẹ̀mí èṣù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù. 21 pẸ̀yin kò lè mu nínú ago tí Olúwa àti ago ti èṣù lẹ́ẹ̀kan náà; ẹ̀yin kò le ṣe àjọpín ní tábìlì Olúwa, àti ni tábìlì ẹ̀mí èṣù lẹ́ẹ̀kan náà. 22 qKí ni ẹ̀ ń gbìyànjú láti ṣe? Àwa ha ń mú Olúwa jowú bí? Àwa ha ní agbára jù ú lọ bi?

Òmìnira àwọn onígbàgbọ́

23 r“Ohun gbogbo ni o yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ń gbe ni rò. 24Má ṣe ronú nípa ara rẹ̀ nìkan; ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù máa wá rere ọmọnìkejì rẹ̀.

25Jẹ ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá ń tà lọ́jà. Má ṣe gbìyànjú láti wádìí lọ́wọ́ ẹni tí ń tà á nítorí ẹ̀rí ọkàn. 26 sNítorí “Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́.”

27Bí ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àsè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àsè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn. 28 tBí ẹnikẹ́ni bá sì kìlọ̀ fún un yín pé, “A ti fi ẹran yìí rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹni ti o sọ fun ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn. 29Èmi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn ẹni tí ó sọ fún ọ kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí kín ni a ó fi dá mi lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn. 30Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, èéṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búburú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.

31Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run. 32 uNítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ tí ó lè gbé ẹlòmíràn ṣubú ìbá à ṣe Júù tàbí Giriki tàbí ìjọ Ọlọ́run. 33 vBí mo ṣè n gbìyànjú láti tẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́rùn nínú gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe láì wa ohun rere fún ara mi bí kò ṣe ti ènìyàn púpọ̀ kí ó lè ṣe é ṣe fún wọn láti le ní ìgbàlà.

Copyright information for YorBMYO