‏ 2 Corinthians 11

Paulu àti àwọn aposteli ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké

1 aMo rò wí pé ẹ ó faradà díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ẹ gbà mí láàyè. 2 bNítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi. 3 cṢùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. 4 dNítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìhìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.

5 eNítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn nínú ohunkóhun sí àwọn àgbà Aposteli. 6 fBí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo. 7 gTàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́. 8 hÈmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín. 9Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀. 10 iÓ jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia. 11 jNítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.

12 kÈmi yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ti èmi ń ṣe láti le mú ìjákulẹ̀ bá àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti bá wa dọ́gba nínú èyí ti àwa ń ṣògo lé lórí. 13Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi. 14Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Satani, tìkára rẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dàbí angẹli ìmọ́lẹ̀. 15Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dàbí àwọn ìránṣẹ́ òdodo; ìgbẹ̀yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

Paulu ṣògo nínú ìjìyà rẹ̀

16Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀. 17 lOhun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí. 18Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú. 19 mNítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. 21Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!

Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú.
22Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 23 nÌránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 24 oNígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 25 pNígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 26 qNí ìrìnàjò nígbàkúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 27 rNínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkúgbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkúgbà, nínú òtútù àti ìhòhò. 28Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. 29 sTa ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?

30Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi. 31Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké. 32 tNí Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Areta fi ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ará Damasku mọ́, ó ń fẹ́ láti mú mi bí arúfin: 33Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Copyright information for YorBMYO