Deuteronomy 2
Ìrìn àrè ní aginjù
1 aNígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí aginjù, a gba ọ̀nà Òkun pupa, bí Olúwa ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Seiri.2Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, 3“Ẹ ti rìn yí agbègbè ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá. 4 bFún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Esau; àwọn ará Edomu tí ń gbé ní Seiri. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi. 5Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí ó ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Seiri fún Esau gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀. 6Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ”
7 Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín. Ó ti mójútó ìrìnàjò yín nínú aginjù ńlá yìí. Olúwa Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogójì ọdún wọ̀nyí, dé bi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.
8Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Esau tí ń gbé ní Seiri. A yà kúrò ní ọ̀nà Arabah èyí tí ó wá láti Elati àti Esioni-Geberi, a sì rìn gba ọ̀nà aginjù Moabu.
9 Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rùba àwọn ará Moabu bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe bá wọn jagun torí pé n kò ní fi èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn fún un yín. Mo ti fi Ari fún àwọn ọmọ Lọti bí i ìní.”
10Àwọn Emimu ti gbé ibẹ̀ rí: Àwọn ènìyàn tó síngbọnlẹ̀ tó sì pọ̀, wọ́n ga bí àwọn Anaki. 11Gẹ́gẹ́ bí Anaki àwọn ènìyàn náà pè wọ́n ní ará Refaimu ṣùgbọ́n àwọn ará Moabu pè wọ́n ní Emimu. 12Àwọn ará Hori gbé ní Seiri kí àwọn ọmọ Esau tó lé wọn kúrò níwájú wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, (wọ́n tẹ̀dó sí ààyè wọn) gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli tí ṣe ní ilẹ̀ tí Olúwa yóò fún wọn ní ìní wọn.
13 Olúwa sì wí pé, “Ẹ dìde, kí ẹ sì la Àfonífojì Seredi kọjá.” Bẹ́ẹ̀ ni a la àfonífojì náà kọjá.
14 cÓ gbà wá ní ọdún méjì-dínlógójì (38) kí ó tó di wí pé a la Àfonífojì Seredi kọjá láti ìgbà tí a ti kúrò ní Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà gbogbo ìran àwọn tí ó jẹ́ jagunjagun láàrín àwọn ènìyàn náà ti ṣègbé kúrò láàrín àwọn ènìyàn náà ní àsìkò yìí bí Olúwa ti búra fún wọn. 15Ọwọ́ Olúwa sì wà lòdì sí wọn nítòótọ́, láti run wọn kúrò nínú ibùdó, títí gbogbo wọn fi run tan.
16Lẹ́yìn tí ẹni tí ó gbẹ̀yìn pátápátá nínú àwọn jagunjagun àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti kú, 17Olúwa sọ fún mi pé, 18“Lónìí ni ẹ̀yin yóò la agbègbè Moabu kọjá ní Ari. 19Bí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Ammoni, ẹ má ṣe halẹ̀ mọ́ wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ bá wọn jagun, torí pé èmi kì yóò fi àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ará Ammoni fún un yín ní ìní. Mo ti fi fún àwọn ọmọ Lọti ní ìní.”
20(A ka ilẹ̀ yìí sí ilẹ̀ àwọn Refaimu, tí wọ́n ti gbé níbẹ̀ rí, ṣùgbọ́n àwọn ará Ammoni ń pè wọ́n ní ará Samsummimu. 21Wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tó lágbára, wọ́n sì pọ̀, wọ́n sì ga gògòrò bí àwọn ará Anaki. Olúwa run wọn kúrò níwájú àwọn ará Ammoni, tí wọ́n lé wọn jáde tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. 22Bákan náà ni Olúwa ṣe fún àwọn ọmọ Esau, tí wọ́n ń gbé ní Seiri, nígbà tí ó pa àwọn ará Hori run níwájú wọn. Wọ́n lé wọn jáde wọ́n sì ń gbé ní ilẹ̀ wọn títí di òní. 23Nípa ti àwọn ará Affimu, tí wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú kéékèèkéé dé Gasa, àwọn ará Kaftorimu, tí wọ́n jáde láti Krete wá ni ó pa wọ́n run, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn.)
Israẹli ṣẹ́gun Sioni ọba Heṣboni
24“Ẹ gbáradì, kí ẹ sì kọjá odò Arnoni. Kíyèsi, Mo ti fi Sihoni ará Amori, ọba Heṣboni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́. Ẹ bá ilẹ̀ náà jagun kí ẹ sì gbà á. 25Èmi bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìbẹ̀rù àti ìfòyà yín sára gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run láti òní lọ. Wọn yóò gbọ́ ìròyìn in yín, wọn yóò sì wárìrì, wọn yóò sì wà nínú ìdààmú ọkàn torí i tiyín.”26Mo rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kedemoti lọ́ sọ́dọ̀ Sihoni ọba Heṣboni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé, 27“Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá. Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan. A kò ní yà sọ́tùn tàbí sósì. 28Ẹ ta oúnjẹ tí a ó jẹ àti omi tí a ó mu fún wa ní iye owó wọn. Kìkì kí ẹ sá à jẹ́ kí a rìn kọjá: 29gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Esau tí ó ń gbé ní Seiri àti àwọn ará Moabu tí ó ń gbé ní Ari, ti gbà wá láààyè títí a fi la Jordani já dé ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò fún wa.” 30Ṣùgbọ́n Sihoni ọba Heṣboni kò gbà fún wa láti kọjá. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí.
31 Olúwa sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kíyèsi i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Sihoni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́. Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀.”
32Nígbà tí Sihoni àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde wá láti bá wa jagun ní Jahasi, 33Olúwa Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀. 34Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátápátá tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí. 35Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa. 36Láti Aroeri, létí odò Arnoni àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa. 37Ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí Jabbok, tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká.
Copyright information for
YorBMYO