‏ Ezekiel 19

Orin ọfọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli

1“Kọ orin ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ-aládé Israẹli 2wí pé:

“ ‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù?
Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
3Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára,
ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.
4Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀,
wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn.
Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.

5“ ‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán,
ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.
6Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára,
o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.
7Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro.
Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.
8Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i,
àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá.
Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un,
wọn sì mú nínú ihò wọn.
9Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli,
wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli.

10“ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀;
tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso,
ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi,
11Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè,
ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀,
gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.
12Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú,
á sì wọ́ ọ lulẹ̀,
afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀,
ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ
iná sì jó wọn run.
13Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀
ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi.
14Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀
ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run,
dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́;
èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’
Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”

Copyright information for YorBMYO