Habakkuk 1
1Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí.Ìráhùn Habakuku
2 a Olúwa, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́,Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi?
Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!”
ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
3Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé
Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà?
Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi;
ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
4Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí,
ìdájọ́ òdodo kò sì borí.
Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká,
Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà.
Ìdáhùn Olúwa
5 b“Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye,Kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi.
Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín
tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́,
bí a tilẹ̀ sọ fún yin.
6 cNítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde,
àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn
tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já
láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn.
7Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà,
ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn,
Yóò máa ti inú wọn jáde.
8Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ,
wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ
àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká;
wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun
9Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá
ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú;
wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.
10Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín
wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé.
Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín;
Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á
11Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà,
yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”
Ìráhùn lẹ́ẹ̀kejì Habakuku
12 Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà?Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú
Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́;
Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí
13Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi;
ìwọ kò le gbà ìwà ìkà
nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè?
Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa
ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?
14Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun,
bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso
15Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè
ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀;
nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.
16Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀,
ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀
nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn
tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
17Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí,
tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?
Copyright information for
YorBMYO